ÌDÌBÒ ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀ TÓ Ń BỌ̀, TA KÍ N TA, LAYÒ FI Í DÙN..!

Bí obìnrin kò jowú,ọbẹ̀ kò lè dùn, méjì mẹ́ta làá m’ẹ́kẹ, èèyàn kan kìí dá ja ìjàkadì kó dùn yùngbà, ìka ẹ̀yọkan kò lè sọ àyà kò ró kìkì! Àti pé ìwọ polówó, èmi ṣe aájò àtità n lariwo fi í pọ̀ lọ́jà!

Ìdùnnú ńlá ló jẹ́ fún àwọn olóye, àti pàápàá ẹgbẹ́ alábùradà tó ń ṣèjọba lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà tí wón gbọ́ ìkéde tí ẹgbẹ́ Olóṣùṣù ọwọ̀ tó jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú ẹgbẹ́ alátakò ní ìpínlẹ̀ yìí ṣe ní òpin ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá pé àwọn ti ṣetán, àwọn sì ti gbáradì láti kópa nínu ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí yó wáyé ní ọdún tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójú tó ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ (OYSIEC) ṣe làá kalẹ̀. Wón ní àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé sọ pé ètò ìdìbò náà kò ní í ní à ń fi epo bọ iyọ̀ nínú, àti pé ẹnikẹ́ni tó bá jáwé olúborí ni àjọ OYSIEC yóò kéde.

Koríko tó tutù ni màlúù ń wá á ká, ibi tó bá tútù ni àdàbà bà sí, ibi tí kòkòrò bá rọ̀sọ̀mù sí la ti í rí lèkélèké, ìgbésẹ̀ ẹgbẹ́ Olóṣùṣù ọwọ̀ ìpínlẹ̀ yìí kò ṣe lẹ́yìn ìwà ọmọlúàbí ti Gómìnà Ṣèyí Mákindé fi tukọ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti bí ọdún mẹ́rin àti oṣù méjì sẹ́yìn, bó ṣe ń ṣe ìjọba àìmẹ̀yà, ìṣèjọba tẹrútọmọ, t’olówó ti mẹ̀kúnnù tó ti mú àlàáfíà àti ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ àti ọ̀nà tí ó ń gbà pín ìpò ìjọba,tí ó ń bù ú re, làá ‘re bí oríkì ọlọ́fàmọjọ̀ káàkiri ẹlẹ́kùn jẹkùn ìpínlẹ̀ yìí ló fún wọn ní ìdánilójú pé yó ṣe bó ṣe wí lórí ọ̀rọ̀ ìdìbò náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn wọn yó ti máa já wọn ní patiẹ pé àwọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí àwọn wà lórí àléfà ìjọba, wọ́n ti gbé ìtìjú tà, wọn ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Olùkọ́ àgbà òṣèlú àsìkò yìí, wọ́n ṣetán láti díje.

Yorùbá ní, ẹran ejò ni màá fi jẹun lálẹ́, àti àárọ̀ la ti í wá a sílẹ̀. Ẹgbẹ́ alábùradà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gbáradì,wọ́n ní ẹni tó bá wẹjú lẹ̀rù ń bà, àti pé “má fi okó mi dá ààlà, àtilẹ̀ la ti í pinwọ́ ẹ̀”, ìdí nìyí tí wọ́n ti fi ṣètò tí wọ́n sì yan àwọn tí wọ́n tó gbangba sùn lọ́yẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùdíje sí ipò alága àti káńsélọ̀ ní tìbútòòró ìjọba ìbílẹ̀ àti wọ́ọ̀dù ìpínlẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé orúkọ Gómìnà Ṣèyí Mákindé tó ní àgúnmu òwò fún gbogbo Olùdíje ẹgbẹ náà nítorí iṣẹ́ ribiribi tí Gómìnà ti gbé ṣe, gbogbo Olùdíje wọ̀nyí ni yó jáde láti yànnàná àwọn ètò tí wón ti piyamọ rẹ̀ kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn agbègbè wọn kárí ilé kárí oko nígbà tí ìpolongo ìbò bá gbérasọ, wọ́n ṣetán láti polongo ìbò, ṣiṣẹ́ kárakára láì dá ibìkan sí.

A dúpẹ́ pé irú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ẹgbẹ alátakò ti ní ìgboyà àti kópa,irú èyí tó ti wáyé ni nǹkan bí ogún ọdún mẹ́rìn-lé-lógún kẹ́yìn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fẹ́ wáyé lásìkò yìí, bùgebùge àkàrà kò sé lẹ́yìn erèé, lààlé àgúnmu kò sé lẹ́yìn ẹ̀kọ yangan, Ìfọgbọ́ntòlú ọmọ Ọlátúnbọ̀sún ló bí àyípadà rere yìí, kí adániwáyé máa bá wa ṣe atọ́nà Gómìnà rere..

© Ayélabẹ́gàn Akínkúnmi Abbas
Ọ̀kan gbòógì nínú ẹgbẹ́ GSM ADVOCATES
*Ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn Ọ̀yọ́
*Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
08134856062

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.