By Muritala S.A
Ká la’jú káyan asojú, ká dijú káyan asojú iyì ibè niwípé k’ásojú jé Olùfokansìn.
Nínú asojú tíó dángàjíá àti tí mùsèmúsé won dámúsémúsé, Ògá ni kanun láwùjo àwon òkúta, Ògá ni iyò láwùjo àwon yèèpè, Ògá l’asojú Àdìgún Abass Agbówórìn láàrín àwon akegbéè.

Tenu kó tètè bòòlì kó, Àdìgún Abass Agbówórìn ti fakoyo, ópegedé, ófi gbòòrò jekà, óti gbóhun ribiribi se láàrín odún méta àti díè séyin.
I. Agbówórìn faná wolé, O s’àtùpà ojà diná mònàmóná, bíe bádé ojà adìe ní mòlété àpeere ún be níbè.

II. Àdìgún Abass kópa ribiribi lórí omi tójá gaara, bíe bádé Ìsàlè Àlúfà Tèmídire Òjé àpeere ún be níbè.
III. Èto Ìlera nko, Adekunle pèsè okò ìgbálódé tiwon ró lágbára ìtójú àìsàn láti máa káàkiri fun ìtójú òfé.
IV. Adékúnlé de ilé kún, ó pèsè yàrá ìkàwé si fáwon akékoo, ara àpeere irú è niti St. Paul Anglican School Yanbule,

V. Agbówórìn túnwò sùnsùn o túnse ìrónilágbára lópò yanturu fáwon arúgbó, òdó ati àwon akékoojáde, ósanwó UTME, WAEC, ó tún sètò èkó òfé fáwon akékoo ilé ìwé gíga, mélo niká kà nínú eyín adípèlé.
E jékí n’so wípé b’éégún eni bájóore orí á yátókùn, àsìkò yí lodù.

Asojú Abass Àdìgún Agbówórìn yíó se léèkan si, èmi wíbè, gbogbo àwon ará, ojúlùmò àti olùdìbò gbùngbùn Àríwá Ìlà Oòrun Ìbàdàn àti Gúúsù Ìlà Oòrun náà si fohùn sòkan pe àwon fowó síi.
